close
Jump to content

Ghusl

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àwọn ohun èlò fún àwọn ìwé àti àlùwàlá nínú ẹ̀sìn àwọn Mùsùlùmí (ní abẹ́lẹ̀) ní Mọ́sálásí Jamek ní Kuala Lumpur, Malaysia

  husl ( jẹ́ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá tí ó túmọ̀ sí ìwíwe gbogbo rra mọ́ tónítóní èyí í ó jẹ́ dandan kí a tó ṣbẹ̀rẹ̀ sí ní e onírúurú ìgbòkègbodò àwa ti àdúrà ẹ̀sìn Màwọn ùsùlùmí. Fún ẹnikẹ́ni nínú Màwọn ùsùlùmí, a máa ṣe é lẹ́yìn ìtí a bá ní bálòpọ̀ (ìyẹn ni pé ó jẹ́ fọ̀ranyàn), kṣáájú í aátó ṣe àdúrà ọjọ́ Ẹtì àti àdúrà fún àwọn ọjọ́ ìsinmi Mùsùlùmí, kí a tó wọ inú iaṣọ hram ní ìmúrasílẹ̀ fún Hajj, lẹ́yìn tí a bkò bá mọ ohun tí à ń ṣe àti lẹ́yìn tí a bá tgbà láti i Mùsùlùmí . Àwọn Mùsùlùmí Sunni tún máa ń ṣe ìwẹ̀ mímọ́ yìí ṣáájú "àdúrà ìrònúpìwàdà".

A máa ń túmọ̀ Ghusl sí "àlùwàlá kíkún", ní ìlòdì sí "àlùwàlá tí kò kún tó" tàbí wudu وضوء èyí tí àwọn Mùsùlùmí máa ń ṣe lẹ́yìn àwọn ẹ̀gbin kékeré bíi ìtọ̀, ìgbẹ́, oorun àsùnnara, àti yíyọ ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ (ó dá lórí madhhab ).

Ghusl jẹ́ ìwẹ̀ ààtò tí ó jẹ́ ọ̀ranyàn. [1] :471

Àwọn oríṣiríṣi ìwẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe ṣe pàtàkì sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ghusl di dandan fún àwọn okùnfà méje kan, àti pé ghusl fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn okùnfà oríṣiríṣi wọ̀nyí ní àwọn orúkọ oríṣiríṣi tí a máa ń pè wọ́n nínú ẹ̀sìn:

  • A máa ń ṣe Ghusl Janabat lẹ́yìn ìbálòpọ̀/ìfọ́njáde àtọ̀.
  • Ghusl Hayd ni àwọn obìnrin máa ń ṣe lẹ́yìn nǹkan oṣù .
  • Ghusl Nifas ní tirẹ̀ máa n tẹ̀lé ẹ̀jẹ̀ ìbímọ (omi tí máa ń jáde lójú ara obìnrin lẹ́yìn ìbímọ, èyí tí ó lè wáyé fún ọ̀sẹ̀ mẹ́fà lẹ́yìn ètò ìbímọ).
  • Ghusl Mayyit jẹ ìwẹ̀ ọ̀ranyàn tí a máa ń ṣe fún àwọn Mùsùlùmí tí wọ́n bá kú tàbí papòdà.

Nínú àwọn ẹ̀ka kan, àwọn ẹ̀ka méjì mìíràn tún ní láti ṣe ghusl:

  • Ghusl Istihada ni àwọn obìnrin kan máa ń ṣe fún sísàn ẹ̀jẹ̀ tí kò tọ́ (láàárín àwọn obìnrin).
  • Ghusl Mas-hil Mayyit di ọ̀ranyàn fún ni nígbà ti ẹnikan ba fi ọwọ́ rẹ̀ kan òkú lára.

Ghusl tún di dandan lẹ́yìn ìjẹ́jẹ̀ẹ́ tàbí ìbúra láti ṣe é.

Àwọn omi tí a nílò

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gẹ́gẹ́ bí ó ti jọ mọ́ àlùwàlá,

Ìwẹ̀ ọ̀ranyàn nílò omi mímọ́, tí kò ní òórùn tí a kò tíì lò fún ohun kankan tẹ́lẹ̀, a ó sì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú kíkéde èrò ìwẹ̀ àti ìjọsìn wa. [2]

Àwọn orísun omi tí a gbà láàyè nìwọ̀nyí :

  • Omi òjò
  • Omi kànǹga
  • Omi orisun, omi òkun, tàbí omi odò
  • Omi yìnyín tí ó ń yọ́
  • Omi ti agbada ńlá kan tàbí adágún-odò kan

A kò gba ìwẹ̀-ọ̀ranyàn láàyè pẹ̀lú omi tí kò mọ́ tàbí èyí tí ó kó ẹ̀gbin sínú tàbí omi tí a fà jáde láti inú èso àti igi.

Àwọn ìṣe ìwẹ̀-ọ̀ranyàn

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Òfin kùránì gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo níyànjú láti má ṣe sún mọ́ ibi tí wọ́n ti ń gbàdúrà nígbà tí wọ́n bá ń sùn títí di ìgbà tí wọ́n bá ti fọ gbogbo ara wọn tán. Irú ohun kan náà ni a ṣe fún àwọn tí wọ́n ti fara kan obìnrin kan, àwọn tí wọ́n ń rìnrìn àjò, àwọn tí wọ́n ń ṣàìsàn, tàbí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ lo ilé ìgbọ̀nsẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ tí wọ́n kẹ́yìn yìí, tí wọn kò bá rí omi, wọ́n lè fi erùpẹ̀ mímọ́ nu ọwọ́ àti ojú wọn.

Àwọn ọ̀mọ̀wé tí wọ́n tẹ̀lé Hanafi túmọ̀ gbólóhùn náà sí “ìbálòpọ̀” nínú ẹsẹ yìí sí ìbálòpọ̀ láàárín akọ àti abo, nígbà tí àwọn Ọmọ̀wé tí wọ́n ń tẹ̀lé Shafi’í túmọ̀ rẹ̀ sí ìbálòpọ̀ nípa fífi ọwọ́ kan àwọn ojú ara àti ìbálòpọ̀ láàárín akọ àti abo. Nítorí náà, ìlé-ẹ̀kọ́ Hanafi ní kò pọn dandan fún ènìyàn láti wẹ ìwẹ̀-ọranyan bí kò bá ti sí ìbálòpọ̀ láàárín obìnrin àti ọkùnrin, nígbà tí ilé-ẹ̀kọ́ Shafi’í ní ó di dandan láti wẹ ìwẹ̀-ọ̀ranyàn ṣáájú kí á tó lè kí ìrun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọn ọ̀ranyàn ti ìwẹ̀-ọ̀ranyàn (Àwọn ìtọ́sọ́nà Hanafi)

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ọ̀ranyàn mẹ́ta ni ó wà tí ó jẹ́ dandan. Tí a bá yọ ẹyọ̀kan nínú àwọn ọ̀ranyàn wọ̀nyí kúrò, a gbọ́dọ̀ dá a padà kí a sì parí rẹ̀ kí a tó parí àwọn tó kù. [3] àwtí wọ́n

  1. Fífi omi fọ inú ẹnu wa (fi omi yọ́ ẹnu).
  2. Fi omi bọ imú (fi omi fọ inú imú) kí o sì fín omi náà jáde.
  3. Fífọ gbogbo ara.

Sùnà Ìwẹ̀-ọ̀ranyàn

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀nà mìíràn tí a lè gbà yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí ànọ́bì Muhammad ti ṣe àfihàn rẹ̀:

  1. Fífọ ọwọ́ méjèèjì títí dé ìgbọ̀nwọ́.
  2. Fífọ àwọn ojú ara kí á sì yọ ìdọ̀tí tàbí ẹ̀gbin kúrò lára (nípa lílo ọwọ́ òsì wa).
  3. Ṣíṣe àlùwàlá (àfọ̀mọ́).
  4. Tú omi sí orí nígbà mẹ́ta, kí á sì fi ọwọ́ pa irun wa kí omi náà lè dé ìsàlẹ̀ irun wa.
  5. Lẹ́yìn náà, wíwẹ ara wa, kí á sì rí i dájú pé omi náà dé gbogbo ara, bẹ̀rẹ̀ láti apá ọ̀tún ara wa lẹ́yìn náà láti apá òsì ara wa, kí á sì fi ọwọ́ pa á kí omi náà lè dé gbogbo ara.

Nínú ẹ̀sìn Islam, ìwẹ̀-ọ̀ranyàn nílò fífọ gbogbo ara. Àwọn ìyàtọ̀ díẹ̀ wà láàárín àwọn ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ nípa Sunni àti ti Shia.

Ilé-ẹ̀kọ́ èrò ti àwọn Sunni

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣe àníyàn (èrò) láti ṣe ìwẹ̀-ọ̀ranyàn, kí o sọ Bismillah kí o sì pinnu láti wẹ ara rẹ mọ́ kúrò nínú àwọn àìmọ́. [3]
  2. Fọ ọwọ́ ọ̀tún dáadáa títí dé ọrùn ọwọ́ (àti àwọn àárín ìka ọwọ́ wa) nígbà mẹ́ta kí á sì rí i dájú pé a fọ̀ wọ́n dáadáa, lẹ́yìn náà kí á ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọwọ́ òsì.
  3. Fífọ àwọn ẹ̀yà ojú ara kí á sì yọ ìdọ̀tí tàbí ẹ̀gbin kúrò lára (nípa lílo ọwọ́ òsì wa).
  4. Ṣíṣe àlùwàlá bí ẹni pé a ṣe é fún ìrun. Kí á rí i dájú pé a fọ ẹnu àti imú wa dáadáa lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Tí a bá bẹ̀rẹ̀ tàbí jókòó lórí òkúta nígbà tí a bá ń wẹ̀, o yẹ kí á fọ ẹsẹ̀ wa nígbà tí a bá ń ṣe àlùwàlá. Ṣùgbọ́n tí o bá jókòó sí ibi tí ẹrẹ̀ wà, a kò gbọdọ̀ fọ ẹsẹ̀ ní àkókò yìí.
  5. A gbọ́dọ̀ da omi sí orí ní ìgbà mẹ́ta kí ó lè máa ṣàn káàkiri ara, kí a sì rí i dájú pé a fọ ìsàlẹ̀ irun àti àwọn apá tí omi kò lè dé bíi ẹ̀yìn orúnkún dáadáa. [4]
  6. Kí á tú omi sí èjìká méjèèjì ní ìgbà mẹ́ta lọ́kọ̀ọ̀kan (bẹ̀rẹ̀ láti èjìká ọ̀tún). A gbọ́dọ̀ gbé ọwọ́ wa káàkiri ara nígbà tí a bá da omi sí i kí apá kan ara má ba à gbẹ.
  7. Kí á lọ sí ibi mímọ́ kí á sì fọ ẹsẹ̀ tí a kò bá wẹ̀ ẹ́ nígbà tí à ń ṣe àlùwàlá.
  8. Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe máa ń ṣe nígbà tí a bá parí àlùwàlá, a gbani nímọ̀ràn láti ka Shahada . [4] [5] [6]

Bí ẹnìkan bá rántí pé apá kan lára ara rẹ̀ ti gbẹ tán lẹ́yìn ìwẹ̀, kò pọn dandan láti tún ìwẹ̀-ọ̀ranyàn ṣe, ṣùgbọ́n kí ẹni náà ó kàn fọ apá ibi tí ó gbẹ náà nìkan ni. Kò tó láti fi ọwọ́ tí ó tutù sí ibi gbígbẹ náà. Tí ẹnìkan bá gbàgbé láti fọ ẹnu tàbí ihò imú, a lè fọ èyí náà nígbà tí a bá rántí pé a kò ṣe é nígbà tí à ń wẹ ìwẹ̀-ọ̀ranyàn. Ó yẹ kí á ṣe ìwẹ̀-ọ̀ranyàn ní ibi ìkọ̀kọ̀ pátápátá.

Nínú ọ̀rọ̀ ànọ́bì Muhammad (kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́run ó lọ máa bá a) mìíràn, Ibn Abbas sọ pé Maymunah bint al-Harith sọ pé wọ́n fún Muhammad ní aṣọ ìnuwọ́ lẹ́yìn ìwé-ọ̀ranyàn, ṣùgbọ́n ó gbọn omi náà dípò kí ó fi nu ara rẹ̀. Ní àfikún, Ibn Abbas kọ sílẹ ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀ pé: Òjíṣẹ́ Allah dá aṣọ ìnuwọ́ tí ó fún un lẹ́yìn ìwẹ̀-ọ̀ranyàn padà, dípò lílò ó.

Àwọn nǹkan tí ó jẹ́ Makruh nínú ìwẹ̀-ọ̀ranyàn

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

wẹ̀ìọ̀ranyàn o

Àwọn nǹkan tí ó jẹ́ makruh nínú ìwẹ̀-ọ̀ranyàn.

  1. Láti wẹ ìwẹ̀-ọ̀ranyàn ní ibi tí ẹnikẹ́ni ti le ní àǹfààní láti máa wò wá.
  2. Wíwẹ́ ìwẹ̀-ọ̀ranyàn ní ìhòhò nígbà tí a bá ń kọjú sí Kaaba .
  3. Sísọ̀rọ̀ nígbà tí a bá ń wẹ̀ lọ́wọ́.
  4. Wíwẹ́ ìwẹ̀
  5. illahàdúrà ó tàtọ̀

í

Ilé-ẹ̀kọ́ èrò àwọn Shia

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀nà méjì ló wà láti wẹ ìwẹ̀-ọ̀ranyàn. A mọ.. ọ̀kan sí ghusl tartibi, èkejì sì ni ghusl irtimasi .

" Ghusl tartibi " túmọ̀ sí wíwẹ̀ pọ́nńbélé, tí a ṣe ní ìpele mẹ́ta.

Lẹ́yìn tí a bá ti fọ àwọn ẹ̀gbin (fún àpẹẹrẹ, àtọ̀ tàbí ẹ̀jẹ̀) kúrò nínú ara àti lẹ́yìn niyyat, a gbọ́dọ̀ fọ ara ní ìpele mẹ́ta: láti orí dé ọrùn; lẹ́yìn náà apá ọ̀tún ara láti èjìká dé ẹsẹ̀; lẹ́yìn náà apá òsì ara.

Ó yẹ kí a fọ apá kọ̀ọ̀kan dáadáa lọ́nà tí omi yóò fi dé awọ ara wa. Ó yẹ kí a ṣọ́ra gidigidi nígbà tí a bá ń fọ orí; a gbọ́dọ̀ fi ìka ọwọ́ ya irun wa (fún àpẹẹrẹ, pẹ̀lú ìka ọwọ́) kí omi lè dé ìsàlẹ̀ irun wa. Nígbà tí a bá ń fọ apá ọ̀tún ara, a gbọ́dọ̀ fọ apá òsì kan náà, àti ní ìdàkejì.

" Ghusl irtimasi " túmọ̀ sí wíwẹ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú rírì gbogbo ara sínú omi. A lè ṣe é nínú omi nìkan, fún àpẹẹrẹ, adágún omi, odò, adágún omi tàbí òkun. Lẹ́yìn tí a bá ti fọ àtọ̀ tàbí ẹ̀jẹ̀ kúrò nínú ara àti lẹ́yìn ìwẹ̀, gbogbo ara gbọ́dọ̀ wọ inú omi pátápátá lẹ́ẹ̀kan náà, kì í ṣe díẹ̀díẹ̀. A gbọ́dọ̀ rí i dájú pé omi náà dé gbogbo ara, títí kan irun àti awọ ara tí ó wà lábẹ́ rẹ̀.

Ghusl tartibi jẹ́ èyí tí a sáábà máa ń ṣe ju ghusl irtimasi lọ.

Àwọn tí a máa ń gbà wẹ ìwẹ̀-ọ̀ranyàn tí a gbani níyànjú

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ohun tí a ti mẹ́nu bà lókè yìí ni àwọn ohun tí ó pọn dandan nínú ìwẹ̀-ọ̀ranyàn; àwọn nǹkan kan wà tí a lè dámọ̀ràn (mustahabb, sunnat) nígbà tí a bá ń ṣe ghusl . Àwọn ìṣe tí a lè dámọ̀ràn wọ̀nyí jẹ́ márùn-ún:

  1. Yíyọ tàbí fífọ ẹnu wa nígbà mẹ́ta àti fífọ imú wa nígbà mẹ́ta.
  2. Ṣíṣe àlùwàlá ṣáájú kí a tó wẹ ìwẹ̀-ọ̀ranyàn.
  3. Fífi ọwọ́ fọ gbogbo ara wa láti rí i dájú pé gbogbo ara ti wẹ̀ dáadáa.
  4. Fífi ìka wa ya irun wa pọ̀ kí omi náà lè dé gbogbo ìsàlẹ̀ irun wa.
  5. (Fún àwọn ọkùnrin) Ṣíṣe istibra' (títọ̀) kí á tó wẹ ghusl janabat . Tí omi bá jáde láti inú nǹkan ọmọkùnrin lẹ́yìn tí a ti parí ghusl náà, tí à sì wá ń ṣiyèméjì bóyá ó jẹ́ àtọ̀ tàbí ìtọ̀, kò nílò láti tún ghusl náà ṣe níwọ̀n ìgbà tí a bá ti tọ̀ kí á tó ṣe ghusl náà. Tí a kò bá tọ̀ kí á tó ṣe ghusl náà, a gbọ́dọ̀ tún n ṣe. Òfin ìtọ̀ yìí kan àwọn ọkùnrin nìkan.
  • Mikvah
  • Tamasha, ìwẹ̀ mímọ́ fún gbogbo ara ti àwọn ará Mandaean
  • Wudu
  • Misogi

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìjápọ̀ òde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Islamic prayer

  1. Mohammad Taqi al-Modarresi (26 March 2016) (in en). The Laws of Islam. Enlight Press. ISBN 978-0994240989. Archived from the original on 2 August 2019. https://web.archive.org/web/20190802163247/http://almodarresi.com/en/books/pdf/TheLawsofIslam.pdf. Retrieved 22 December 2017.
  2. Empty citation (help)
  3. 1 2 Pānīpatī, Muḥammad S̲anāʾullāh (1985-01-01) (in en). The Essential Hanafi Handbook of Fiqh. Kazi Publications. p. 39. https://books.google.com/books?id=I4QwAAAAYAAJ.
  4. 1 2 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named "islamqa2".
  5. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named "sahihbukhari".
  6. Empty citation (help)